Aláàfin Adéyemí Pé Àádóta Odún Lórí Ìté, K’Óba Ñlá Pé Kánrinkése – Adelabu
Aláàfin Adéyemí Pé Àádóta Odún Lórí Ìté, K’Óba Ñlá Pé Kánrinkése – Adelabu
“Láyé Olúgbón, mo dá borùn méje/
E ò maa fi wé lórin/
Láyé Arèsà,, mo dá borùn mefà/
E ò maa fi wé lórin/
Láyé Àtàndá, mo ra kókò, mo r”àrán, mo ra sányán baba aso/
Àf’òle ló lè pé lè yí ò dûn, à f’òle!/
ALÁÀFIN OLÁYÍWOLÁ ADÉYEMÍ PÉ ÀÁDÓTA ODÚN LÓRÍ ÌTÉ, K’ÓBA ÑLÄ Ó TÚN PÉ KÁNRINKÉSE
ÌLÚ ñ so, Aro ñ dún, fèrè ñ fon béè ni sèkèrè ñ mì l’ójó t’óba wa gb’adé ní ojúde Durbar l”alede Ôyó Aláàfin. Ìyen l’ójó kerìnlá, osù kínní, odún 1971. Ó bùse gàdà, ó bùse gèdé, ni Kábíyèsí Aláyélúwà, ikú Bàbà, Yèyè, Aláàfin Làmídì Oláyíwolá Àtàndá Adéyemí Eléèketa bá pé àádóta odún lórí ìté àwon baba ñláa won l’ójó kerìnlá, osù kínní odún 2021.
KÒ wáá sí ohun à bá fi f’áyò lórí àkókò Kábíyèsí Oba Oláyíwola Adéyemí bí ò bá s’opé àti òsûbà bàñbà láti àádóta odún séyìn. Láti ìgbà t’Aláàfin Adéyemí ti gorí ìté, eku ñ ké bí eku, eye ñ ké bí eye, aboyún ñ bí wéré, àgàn ñ t’owó ààlà b’osùn. Béè sì tùn n’igbá ilé ò fó, àwo ilé náà ò sì tún f’à ya.
LÁÀRIN àádóta odún t’Óba Adéyemî ti ñ gbórí ìté s’olá, òpòlopò ìlosíwájú àti ìdàgbàsókè ló ti bá ìlú Òyó Aláàfin, Îpínlè Òyó lápapò àti gbogbo Ìwò Oòrùn Ilè Yorùbá pâtápátá n’íbi tí Kábíyèsí Ikú, Bàbá, Yèyé ti ñ se Oba àkókó, tí gbogbo àwon Oba aládé yòókù ñ wáríí fún!
INÚ mi dùn láti kíyèsi pé láti ìgba tí Bàbá mi Aláàfin Àtàndá omo Oba Adéyemí kejì ti g’orí îté, orísirísi ìjoba ológun àti ìjoba olósèlú àwaarawa ni Kábíèsí ti bá sisé. Lóòrè kóòrè àti àtìgbàdégbà ni Aláàfin gbogbo ilèé káàrò oò jíire bí sì máa ñ fún àwon ìjoba tó ti tó bíi mókànlélógún séyîn ní ìmòràn, ìfowósowópò àti àtìleyìn tó gbon ñ gbón. Àwon ìmòràn àti àtìleyìn àtîgbàdégbà wònyí ló sì jé òpákùtèlè òpòlopò àseyorí tí àwon ìjoba tó ti kojá wònyí se.
BÀBÁÀ mi Aláàfin, omo Ikú t’íkú ò leè pa, Bàáà mi, èyin omo Àrùn t’árùn ò leè gbé dè. E dákun, e jé ñ wúre béléñja fún yín láyájó àádóta odún tée ti wà l’órí àlééfà àwon baba yín tó ti wo káà ilè rèé sùn, rèé sinmi.
BÁÀMI Aláàfin Òyó, mo ní kée gbó, mo ní kée tó. Mo ní b’írùkèrè kan bá ti ñ d’okini, béè l’òmíì ó máa ró’pòo rè tí ó sì máa pò si yetuyetu, kánrin kése, Esin Oba a je’ko pépéépé o! À s’odún m’ódún wáá l’awo àsodúnmódún, à sosù mósû l’awo àsosù m’ósù. Igba odún, bí odún kan ni ko je fún yín Baba tia. Lásìkòo Oba ñlá Adéyemí Àtàndá táa wà yi, îlú yóò r’ójú, àwa èèyan inú rè á r’áyè Àní láròókò t’èyin, gbogbo ilèe Yóòbá ò ní méérí. Iwájú, iwájú l’òpá èbìtì àwa omo káàrò aà jí bí ó màa ré sí n’ìgbà té ñ gbórí ìté p”àse!
MO ti wáá wúre òhún bùse l’óláa yín, l’ólá àwon tó n’ilè àti l’ólá Elédùmarè t’O télè bí ení téní. Bí mo bá wáá dúró tí mo wúre, ìree mi kò sài gbà dandan. Bí mo sì bèrè tí mo wúre, ìree mi kò sàì gbà dandan.
KÁBÍÈSÍ Aláàfin Oláyíwolá Adéyemí, léèkan si, mo kíi yín kú oríire àádóta odún lórí ìté àwon Aláàfin Òyó tó ti lo. Kée gbó, kée tó, kée pé kánrin kése o!
KÁÁÁBÍÈSÍ o, Aláse, èkeji Òrìsà!
ADÉBÀYÒ OMO ADÉLABÚ
ÌBÀDÀN
14/01/2021 .”